Skip to content
New issue

Have a question about this project? Sign up for a free GitHub account to open an issue and contact its maintainers and the community.

By clicking “Sign up for GitHub”, you agree to our terms of service and privacy statement. We’ll occasionally send you account related emails.

Already on GitHub? Sign in to your account

i18n: init Yoruba (yo) locale #14241

Merged
merged 2 commits into from
Oct 30, 2024
Merged
Show file tree
Hide file tree
Changes from all commits
Commits
File filter

Filter by extension

Filter by extension

Conversations
Failed to load comments.
Loading
Jump to
Jump to file
Failed to load files.
Loading
Diff view
Diff view
8 changes: 8 additions & 0 deletions i18n.config.json
Original file line number Diff line number Diff line change
Expand Up @@ -487,6 +487,14 @@
"langDir": "ltr",
"dateFormat": "MM/DD/YYYY"
},
{
"code": "yo",
"crowdinCode": "yo",
"name": "Yoruba",
"localName": "Yorùbá",
"langDir": "ltr",
"dateFormat": "MM/DD/YYYY"
},
{
"code": "zh-tw",
"crowdinCode": "zh-TW",
Expand Down
166 changes: 166 additions & 0 deletions public/content/translations/yo/dao/index.md

Large diffs are not rendered by default.

191 changes: 191 additions & 0 deletions public/content/translations/yo/decentralized-identity/index.md

Large diffs are not rendered by default.

357 changes: 357 additions & 0 deletions public/content/translations/yo/defi/index.md

Large diffs are not rendered by default.

138 changes: 138 additions & 0 deletions public/content/translations/yo/desci/index.md

Large diffs are not rendered by default.

Original file line number Diff line number Diff line change
@@ -0,0 +1,73 @@
---
title: Bí a ṣe lè "ṣẹ̀dá" àkántì Ethereum kan
description: Ìgbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan lórí ìtọ́sọ́nà ìṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù pẹ̀lú lílo àpamọ́wọ́.
lang: yo
---

# Bí o ṣe lè ṣẹ̀dá àkántì Ethereum kan

**Ẹnikẹ́ni lè ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Ethereum l'ọ̀fẹ́. ** O kàn ní láti fi ohun èlò ìfowópamọ́ kírípítò sórí ẹ̀rọ̀ rẹ. Ìṣẹ̀dá àwọn àpamọ́wọ́ àti Ìṣakóso àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù rẹ. Wọ́n lè fi ìnáwó ránṣẹ́, ṣàyẹ̀wò owó rẹ, kí wọ́n sì so ọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ohun èlò mìíràn tí wọ́n kọ sórí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù.

Pẹ̀lú àpamọ́wọ́ kan o tún le wọlé sí èyíkèyí pàṣípààrọ̀ tọ́kẹ̀n, àwọn eré, àwọn ọjà [NFT](/glossary/#nft) lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kò sí ìdí fún ìforúkọsílẹ̀ ẹyọ kọ̀ọ̀kan, àkọọ́lẹ̀ kan ni a pín fún gbogbo àwọn ohun èlò tí a kọ sórí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù.

## Ìgbésẹ̀ 1: Yan àpamọ́wọ́ kan

Àpamọ́wọ́ jẹ́ ohun èlò tí ó ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣakoso àkáǹtì Ethereum rẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpò owó ló wà láti yàn nínú wọn: orí ẹ̀rọ alágbèéká, orí kọ̀ǹpútà alágbèéká, tàbí àwọn àfikún ìwífún aṣàwákiri pàápàá.


<ButtonLink href="/wallets/find-wallet/">
Àtòjọ àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì
</ButtonLink>

Tí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí Kírípítò, o le yan aṣẹ̀yàn "Kiripito tuntun" ní orí pápá "wa àpamọ́wọ́" láti ṣe ìdánimọ̀ àwọn àpamọ́wọ́ tí ó máa kó gbogbo ẹ̀yà tí o wúlò fún ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.

![Aṣayan aṣẹ́ lórí ojúewé 'wá àpamọ́wọ́](./wallet-box.png)

Àwọn aṣẹ̀yàn prófáìlì mìíràn tún wà láti ṣe àbójútó àwọn àìní rẹ. Àpẹẹrẹ àwọn àpamọ́ owó tí wọ́n sábà máa ń lò nìwọ̀nyí - ó yẹ kí o ṣe ìwádìí tìrẹ kí o tó fọkàn tán ètò èyíkéyìí.

## Igbesẹ 2: Ṣe igbasilẹ ohun elo apamọwọ ki o fi sori ẹrọ rẹ

Lọgan ti o ba ti pinnu lori apamọwọ kan pato, lọ si oju opo wẹẹbu ojulowo wọn tabi itaja ohun elo, ṣe igbasilẹ ki o si fi si ori ẹrọ rẹ. Gbogbo wọn ló yẹ kó wà lọ̀fẹ́.

## Igbesẹ 3: Ṣí ohun èlò náà kí o ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù rẹ

Ní ìgbà àkọ́kọ́ tí o bà ṣí àpamọ́wọ́ tuntun rẹ ó le bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ẹ láti yàn láàrin ṣìṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ tuntun tàbí gbígbé ọ̀kan tí ó wà tẹ́lẹ̀ wọlé. Tẹ̀ sórí ìsẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ tuntun. **Èyí ni ìgbesẹ̀ nígbà tí àpamọ́wọ́ sọ́fítíwià ń ṣe àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù rẹ**

## Ìgbésẹ̀ 4: Fi gbolohun olùgbàpadà rẹ pamọ́

Díẹ̀ nínú àwọn ohun èlò yóò bèèrè fún ọ láti kọ àṣírí pamọ́ "gbolohun olùgbàpadà" (nígbà míì wọ́n ń pè ní "gbólóhùn irugbin" tàbí "mnemonic"). Fí fi àwọn gbólóhùn yíì pamọ́ ṣe pàtàkì gidi gan! Èyí ni à ń lò láti ṣe àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù rẹ àti pé o le lòó láti fi àwọn ìṣòwò ránṣẹ́.

**Ẹnikẹ́ni tó bá mọ gbólóhùn náà lè wà ní àkóso gbogbo owó rẹ.** Má ṣe sọ èyí fún ẹnikẹ́ni. Ọ̀rọ̀ yìí gbọ́dọ̀ ní ọ̀rọ̀ méjìlá sí mẹ́rìnlélógún tí wọ́n dá sílẹ̀ lóòrèkóòrè (ọ̀nà tí wọ́n gbà tòó ọ̀rọ̀ náà ṣe pàtàkì).

<div>
<InfoBanner shouldSpaceBetween emoji=":eyes:">
<div><b>Ṣé àpamọ́wọ́ ti wà ní orí ẹ̀rọ àgbéká rẹ?</b><br/> Kọ́ bí o ṣe le lòó.</div>
<ButtonLink href="/guides/how-to-use-a-wallet">
Bí o ṣe lè lo wọ́lẹ́ẹ́tì kan
</ButtonLink>
</InfoBanner>
</div>

Ṣé o fẹ́ mọ àwọn ìtọ́sọ́nà míì? Ṣàyẹ̀wò àwọn: [ìtọ́nisọ́nà ìgbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan](/guides/) wa

## Awon ibere gbogbo ìgbà

### Ṣé ìkan náà ni àpamọ́ owó mi àti àkáǹtì Ethereum mi?

Rara. Àpamọ́wọ́ jẹ́ ohun èlò ìṣàkóso tí ó ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣètò àwọn àkáǹtì. Àpamọ́wọ́ ẹyọ ọ̀kan le wọlé sí àwọn àkọọ́lẹ̀ púpọ̀, àti pé àkọọ́lẹ̀ kan le gba àwọn àpamọ́wọ́ púpọ̀. Ọ̀rọ̀ olùgbàpadà ni a ń lò láti ṣẹ̀dá àwọn àkọọ́lẹ̀ àti fún àṣẹ fún ohun èlò àpamọ́wọ́ láti ṣakoso àwọn ohun ìní.

### Ṣé mo lè fi Bitcoin ránṣẹ́ sí adirẹsi Ethereum, tàbí ether sí adirẹsi Bitcoin?

Rárá o, o ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bitcoin àti ether wà lórí àwọn nẹ́tíwọ́ọ̀kì ọ̀tọ̀tọ̀ méjì (ie àwọn blockchains ọ̀tọ̀tọ̀), ọ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lu ìwé-ìpamọ́ tirẹ̀ àti àwọn ọ́nà àdírẹ́sì tirẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbìyànjú ló ti wà láti ṣe afárá àwọn nẹ́tíwọ̀ọ̀kì oríṣi méjì, nínú èyítí ọ̀kan tí ó ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni [Wrapped BTC tàbí WBTC](https://www.bitcoin.com/get-started/what-is-wbtc/). Èyí kìí ṣe ìfọwọ́sí, nítorí WBTC jẹ́ ojútùú ti olùbánifipamọ́ (ìtumọ̀ pé ẹgbẹ́ kan tí àwọn ànìyàn kan ṣàkóso àwọn iṣẹ́ pàtàkì) àti pé a pèsè rẹ níbí fún àwọn àlàyé nìkan ni.

### Tí mo bá ní àdírẹ́sì ETH kan, ṣé mo ní adirẹsi kan náà lórí àwọn blockchains míràn?

O le lo [àdírẹ́sì](/glossary/#address) kan náà lórí gbogbo àwọn blockchains tí o ń lo irú sọ́fítíwià ìpìlẹ̀ sí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù (tí a mọ̀ bíi 'ibamu-EVM'). [Àtòjọ](https://chainlist.org/) yìí yóò fi hàn ọ́ àwọn blockchain tí o lè lò pẹ̀lú àdírẹ́sì kan náà. Díẹ̀ nínú àwọn blockchain, bí Bitcoin, ṣe ìmúse ìṣètò sí nẹ́tíwọ̀ọ̀kì tí ó yàtò pátápátá àti wípé o yóò nílò àdírẹ́ẹ̀sì tó yàtọ̀ pẹ̀lú ọ̀nà tó yàtọ̀. Tí o bá ní àpamọ́wọ́ àdéhùn ọlọ́gbọ́n kan, ó yẹ kí o ṣ'àyẹ̀wò ojú òpó wẹ́ẹ̀bù rẹ fún irú àwọn blockchain tí ó ṣe àtìlẹ́yìn fún nítorí ní gbogbo ìgbà, wọ́n má ń ní ààlà tí ó mọ níwòn ṣùgbón ààbò kíkún.

### Ǹjẹ́ níní àpamọ́wọ́ tèmi lọ́wọ́ á dáàbò bò mí ju pé kí n kó owó mi sórí àpamọ́wọ́ tí àwọ́n pàsípáàrọ̀?

Tó o bá ní àpamọ́wọ́ tìrẹ, ìyẹn á jẹ́ kó o lè dáàbò bo àwọn ohun ìní rẹ. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìfowópamọ́ tó ti kùnà ti pàdánù owó àwọn oníbàárà wọn. Níní àpamọ́wọ́ kan (pẹ̀lú ọ̀rọ̀ gbólóhùn olùràpadà) mú ewu tó so mọ́ ìṣègbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹgbẹ́ kan láti tọ́jú àwọn ohun ìní rẹ. Àmọ́, o ní láti dáàbò bò ó fúnra rẹ, kí o sì yẹra fún àwọn ète ìtànjẹ, bíbuwọ́lu ìṣòwò láìsí ìdí tàbí ṣíṣí ọ̀rọ̀ gbólóhùn olùràpadà sílẹ̀, lílọ sí àwọn ìkànnì ayédèrú àti àwọn ewu ààbò ara ẹni mìíràn. Àwọn ewu àti àǹfààní tó wà nínú rẹ̀ yàtọ̀ síra.

### Bí mo bá pàdánù fóònù mi/àpamọ́wọ́ alágbèéká mi, ṣé mo ní láti tún lo ẹ̀rọ àpamọ́wọ́ kan náà láti gba owó tí mo pàdánù padà?

Rárá, o lè lo àpamọ́wọ́ míì. Níwọ̀n ìgbà tóo bá ti ní gbólóhùn ìkọ̀kọ̀ náà o lè tẹ̀ ẹ́ sínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpamọ́ owó wọn yóò sì dá àkáǹtì rẹ padà. Ṣọ́ra tí o bá nílò láti ṣe èyí: ó dára jùlọ láti ríi dájú pé o kò ní àsopọ̀ sí orí íńtánẹ̀ẹ̀tì nígbàtí o bá ń gba àpamọ́wọ́ rẹ padà kí gbólóhùn ọ̀rọ̀ olùgbàpadà rẹ má ba ṣí sílẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Ó sábà máa ń ṣòro láti gba owó tó bá sọnù padà láìsí gbólóhùn olùgbàpadà náà.
Original file line number Diff line number Diff line change
@@ -0,0 +1,97 @@
---
title: Bí o ṣe le mọ àwọn àmi ẹ̀tàn
description: Mímọ̀ nípa àwọn àmì ẹ̀tàn, bí wọ́n ṣe ń mú kí ara wọn jẹ́ ògidì, àti bí a ṣe lè yẹra fún wọn.
lang: yo
---

# Bí o ṣe le mọ àwọn àmi ẹ̀tàn {#identify-scam-tokens}

Ọ̀kan lára àwọn ohun tí wọ́n sábà máa ń lò Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù fún ni kí ẹgbẹ́ kan ṣẹ̀dá tọ́kẹ̀n kan tí o ṣe é tà, èyí tó dàbí owó tiwọn. Àwọn tọ́kẹ̀n yìí má ń tẹ̀lé àwọn ìlànà, [ERC 20](/developers/docs/standards/tokens/erc-20/). Àmọ́ ṣá o, níbikíbi tí òfin bá ti fàyè gba àwọn nǹkan tó níye lórí, àwọn ọ̀daràn tó máa ń gbìyànjú láti jí nǹkan tó níye lórí náà máa ń wà.

Ọ̀nà méjì ni wọ́n lè gbà láti tàn ẹ́ jẹ:

- **Títa ẹ̀dà owó àmi ẹ̀tàn kan fún ọ**, èyí tó lè dà bí tọ́kẹ̀n tó jẹ́ ògidì, ṣùgbọ́n tí àwọn oní jìbìtì ṣe, tí kò sì níye lórí rárá.
- **Títan ni jẹ láti buwọ́lu àwọn àdéhùn tí ó jẹ́ ayédèrú ìṣòwò**, lọ́pọ̀ ìgbà nípa dídarí rẹ lọ síbi ohun elo tiwon. Wọ́n lè gbìyànjú láti mú kí o fún àwọn àdéhùn wọn ní owó òòyà lórí àwọn tọ́kẹ̀n ERC-20 rẹ, èyí tí yóò tú àṣírí àwọn ìsọfúnni rẹ tó ṣe kókó, tí yóò fún wọn ní ààyè sí àwọn ohun ìní rẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ojúewé oníṣe wọ̀nyí lè jẹ́ àdàkọ tí ó fẹ̀ẹ́ fara pẹ́ ti àwọn ojúewé tí ó jẹ́ ògidì, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ẹ̀tàn tí ó pamọ́.

Láti ṣe àpèjúwe àwọn àmì ẹ̀tàn yìí, a yóò wo àpẹrẹ kan: [`wARB`](https://etherscan.io/token/0xb047c8032b99841713b8e3872f06cf32beb27b82). Tọ́kẹ̀n yìí ń gbìyànjú láti dàbí àmì [`ARB`](https://etherscan.io/address/0xb50721bcf8d664c30412cfbc6cf7a15145234ad1) tí ó jẹ́ ògidì.

<ExpandableCard
title="Kini ARB?"
contentPreview=''>

Arbitrum jẹ́ àgbájọ tí ó ń ṣe àgbékalẹ̀ àti ìṣàkóso àwọn ohun èlò <a href="/developers/docs/scaling/optimistic-rollups/">optimistic rollup</a>. Ní àkọ́kọ́, wọ́n ṣ'èdá Arbitrum gẹ́gẹ́ bíi ilé iṣé tí kìí ṣe fún èrè, sùgbọ́n lẹ́hìn náà gbé ìgbésẹ láti jẹ́ aláìní ìṣàkóso. Gẹ́gẹ́ bíi ara ètò náà, wọ́n ṣe àgbéjáde <a href="/dao/#token-based-membership">tọ́kẹ̀n ìṣàkóso</a> tí o ṣe ṣòwò.

</ExpandableCard>

<ExpandableCard
title="Kí ló dé tí wọ́n fi ń pe tọ́kẹ̀n ayédèrú náà ní wARB?"
contentPreview=''>

Ìṣe kan wà ní Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù tí ó jẹ́ pé tí ohun ìní kan kò bá bá ìlànà ERC-20 mú, a ṣ'èdá ẹ̀dà irú àmì náà "àfiwé" pẹ̀lú tí orúkọ wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú "w". Nítorí náà, fún àpẹrẹ, a ní wBTC fún Bitcoin àti <a href="https://cointelegraph.com/news/what-is-wrapped-ethereum-weth-and-how-does-it-work">wETH fún Ether</a>.

Kò ní ìtumọ̀ láti ṣ'èdá ẹ̀dà tọ́kẹ̀n ERC-20 tí ó ti wà ní orí Ethereum, sùgbọ́n àwọn oní jìbìtì gbéra le ìfarajọ àmì ti ògidì dípò òtítọ́ tí ó wa níbẹ̀.

</ExpandableCard>

## Báwo ni àwọn tọ́kẹ̀n ẹ̀tàn ṣe ń ṣiṣẹ́? {#how-do-scam-tokens-work}

Gbogbo ohun tí Ethereum wà fún ni aláìní ìṣàkóso. Èyí túmò sí pé kò sí aláṣẹ àárín gbùngbùn tí o le gba àwọn òhun ìní rẹ tàbí ṣe ìdíwọ́ fún ọ láti ṣe àgbéjáde àdéhùn ọlọ́gbọ́n. Àmọ́ ó túmọ sí pé àwọn oní jìbìtì le ṣe àgbéjáde àdéhùn ọlọ́gbọ́n tó wù wọ́n.

<ExpandableCard
title="Kini awọn adehun ọlọgbọn?"
contentPreview=''>

<a href="/developers/docs/smart-contracts/">Àdéhùn ọlọ́gbọ́n</a> jẹ́ àwọn ètò tí ó n ṣiṣẹ́ ní orí ẹ̀rọ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù. Fún àpẹrẹ, gbogbo tọ́kẹ̀n ERC-20 tí a ṣe ní àdéhùn ọlọ́gbọ́n.

</ExpandableCard>

Ni pato, Arbitrum gbe adehun kan ti o lo aami `ARB`. Ṣugbọn iyẹn ko da awọn eniyan miiran duro lati tun gbe adehun ti o lo aami kanna gangan, tabi ọkan ti o jọra. Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìwé àdéhùn náà ló máa pinnu ohun tí ìwé àdéhùn náà máa ṣe.

## Kò dà bí Ojúlówó {#appearing-legitimate}

Àwọn ẹ̀tàn bíi mélòó kan wà tí àwọn tó ń ṣe ayédèrú tọ́kẹ̀n máa ń lò láti farahàn bíi Ojúlówó.

- **Orúkọ àti àmì ti ojúlówó**. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn àdéhùn ERC-20 le ní àmì àti orúkọ kannáà bí àwọn àdéhùn ERC-20 mìíràn. O ò le gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọ̀nà yìí fún ààbò.

- **Oní ǹkán lọnà òtítọ́**. Àwọn àmì ẹ̀tàn nígbàgbogbo má ń ṣe ìfiránṣẹ́ àwọn iye owó tó pọ̀ sínú àdírẹ́ẹ̀sì tí ó dàbí ojúlówó oníhun àwọn tọ́kẹ̀n ojúlówó.

Fún àpẹrẹ, ẹ jẹ ká tún wo `wARB` lẹ́ẹ̀kansi. [Ó fẹ́rẹ̀ tó 16% àwọn tọ́kẹ̀n yìí](https://etherscan.io/token/0xb047c8032b99841713b8e3872f06cf32beb27b82?a=0x1c8db745abe3c8162119b9ef2c13864cd1fdd72f) tí ó wà nínú àwọn àdírẹ́ẹ̀sì tí ìdánimọ̀ wọn jẹ́ [Arbitrum Foundation: Deployer ](https://etherscan.io/address/0x1c8db745abe3c8162119b9ef2c13864cd1fdd72f) tí ó farahàn sí gbogbo èèyàn. Èyí _kìí ṣe_ àdírẹ́ẹ̀sì èké, kódà, ó jẹ̀ àdírẹ́ẹ̀sì tí ó lo àdéhùn ARB tòótọ́ [lórí ẹ̀rọ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù](https://etherscan.io/tx/0x242b50ab4fe9896cb0439cfe6e2321d23feede7eeceb31aa2dbb46fc06ed2670).

Nítorí pé iye owó ti àdírẹ́ẹ̀sì ERC-20 jẹ́ ọ̀kan lára ìpamọ́ àdéhùn ERC-20, ó lè jẹ́ èyíkèyí tí àdéhùn náà bá sọ pé ó jẹ́. Ó tún ṣeé ṣe fún àdéhùn láti dènà ìfowóránṣẹ́ láti máà jẹ́ kí àwọn ojúlówó olùmúlò baà lè má kó àwọn ayédèrú tọ́kẹ̀n wọ̀nyẹn kúrò.

- **Ìfowóránṣẹ́ ojúlówó: **. _Àwọn oní ńkan tó jẹ́ ojúlówó kò ní sanwó láti fi tọ́kẹ̀n ẹ̀tàn ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn, nítorí náà, bí wọ́n bá fi owó ránṣẹ́, ó ní láti jẹ́ èyí tó tó jẹ́ ojúlówó àbí?_**bẹ́ẹ̀ kọ́**. `Àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìfiránsẹ́` ni a ṣe nípasẹ̀ àdéhùn ERC-20. Ẹni tó ń tanni jẹ lè kọ ìwé àdéhùn náà lọ́nà tó máa mú kó ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

## Àwọn ìkànnì ayédèrú {#websites}

Àwọn oníjìbìtì tún lè ṣe àwọn ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó dáńgájíá gan-an, nígbà míì wọ́n lè ṣe àdàkọ ojúlówó ìkànnì pẹ̀lú àwọn àdàkọ UI tó fara jọra, àmọ́ wọ́n máa ń lo àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí kò farahàn. Àpẹẹrẹ lè jẹ àwọn ojú ọ̀nà ìtọ́kasí ti orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí ó farajọ ojúlówó sùgbọ́n tí ó ń gbé àwọn olùṣàmúlò lọ sí ojú-ewé ẹ̀tàn mìíràn, tàbí àwọn ìkànnì tí kò tọ̀nà tí ó ń darí olùṣàmúlò láti fi àwọn bọ́tìnì ìpamó wọn hàn tàbí tí ó ń rán owó lọ sí àdírẹ́sì oní jìbìtì.

Ohun tó dára jù lọ láti yẹra fún èyí ni láti farabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò URL fún àwọ ìkànnì tí o lọ, kí o sì fi àwọn àdírẹ́ẹ̀sì fún àwọn ìkànnì tí o mọ̀ pé ó jẹ́ ojúlówó sínú àwọn àlàfo rẹ. Lẹ́yìn náà, o lè wọlé sí ojúlé ojúlówó náà nípasẹ̀ àwọn àlàfo rẹ láìṣe àṣìṣe tàbí gbígbára lé àwọn ọ̀nà ìtọ́kasí ìta.

## Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ? {#protect-yourself}

1. **Ṣàyẹ̀wò àdírẹ́sì àdéhùn náà**. Àwọn tọ́kẹ̀n ojúlówó wá látọ̀dọ̀ àwọn àjọ ojúlówó o sì lè rí àwọn àdírẹ́sì àdéhùn náà lórí ìkànnì àjọ náà. Fún àpẹẹrẹ, [fún `ARB` o le wo àwọn àdírẹ́sì tí ó tọ́ níbí](https://docs.arbitrum.foundation/deployment-addresses#token).

2. **Àwọn tọ́kẹ̀n gidi ní owó tí wọ́n ń ná**. Ọ̀nà mìíràn ni láti wo ìwọ̀n owó lórí [Uniswap](https://uniswap.org/), ọ̀kàn nínú àwọn ìlànà pàsípààrọ̀ tọ́kẹ̀n tí ó wọ́pọ̀ jùlọ. Ìlànà yìí ń ṣiṣẹ́ nípa lílo adágún owó fún ìṣòwò, nínú èyí tí àwọn olùdókòòwò fi àwọn tọ́kẹ̀n wọn sínú ní ìrètí fún èrè láti ìdíyelé ìṣòwò.

Àwọn tọ́kẹ̀n èké sábà máa ń ní owó kékeré, bí ó bá ní rárá, nítorí pé àwọn oníjìbìtì kì í fẹ́ fi àwọn ohun ìní gidi wewu. Fun apẹẹrẹ, adágún `ARB`/`ETH `Uniswap ní bíi mílíọ̀nù kan dọ́là ([wòó níbí fún iye tó jẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́](https://info.uniswap.org/#/pools/0x755e5a186f0469583bd2e80d1216e02ab88ec6ca)) àtipé rírà àti títà iye kékeré kò le yí iye owó padà:

![Ríra tọ́kẹ̀n òtítọ́](./uniswap-real.png)

Sùgbọ́n nígbàtí o bá gbìyànjú láti ra tọ́kẹ̀n ẹ̀tàn `wARB`, kódà ìṣòwò kékeré kan yóò yí iye owó padà ní ìdá àádọ́rùn-ún – 90%:

![Ríra tọ́kẹ̀n ayédèrú](./uniswap-scam.png)

Èyí tún jẹ́ ẹ̀rí mìíràn tó fi hàn pé kò ṣeé ṣe kí `wARB`jẹ́ tọ́kẹ̀n ti ojúlówó.

3. **Wo inú Etherscan**. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tọ́kẹ̀n ayédèrú ni a ti mọ̀ tí àwọn ará àwùjọ ti ròyìn wọn. Irú àwọn tọ́kẹ̀n bẹ́ẹ̀ ni a [fi àmì sí nínú Etherscan](https://info.etherscan.com/etherscan-token-reputation/). Lóòótọ́ Etherscan kìí ṣe orísun àṣẹ ti òtítọ́ (ó jẹ́ ìṣẹ̀dá tí àwọn nẹ́tíwọ̀ọ̀kì tí kò ní àkóso pé kò le sí orísun apàṣẹ fún ìfúnni ní ojúlówó), àwọn tọ́kẹ̀n tí Etherscan ṣe ìdánimọ̀ bí ayédèrú ṣe é ṣe kò jẹ́ ayédèrú.

![Ayédèrú tọ́kẹ̀n ní orí Etherscan](./etherscan-scam.png)

## Conclusion {#conclusion}

Níwòn ìgbà tí iye bá wà ní àgbáyé, àwọn oní jìbìtì yóò wà tí yóò gbìyànjú láti jalè iye náà fún ara wọn. Àti pé, ní àgbáyé tí kò ní àkóso àárín gbùngbùn, kò sí ẹnikẹ́ni láti dáàbòbo ìwọ àyàfi ara rẹ. A nírètí wípé óò rántí àwọn kókó wọ̀nyí láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dá àwọn ojúlówó tọ́kẹ̀n yàtọ̀ sí àwọn ayédèrú:

- Àwọn tọ́kẹ̀n ayédèrú ṣe bí àwọn tọ́kẹ̀n tòótọ, wọn le lo orúkọ kannáà, àmì ìdánimọ̀ kànnà, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
- Àwọn tọ́kẹ̀n ayédèrú _kò le_ lo àdírẹ́ẹ̀sì àdéhùn kannáà.
- Orísun tó dára jùlọ fún tọ́kẹ̀n tí o jẹ́ ojúlówó ní ìkànnì àgbájọ tí o ṣe tọ́kẹ̀n náà.
- Tí o bá kùnà ìyẹn, o le lo ohun èlò gbajúgbajà, tí o ṣe f'ọkàn tán bíi [Uniswap](https://app.uniswap.org/#/swap) àti [Etherscan](https://etherscan.io/).
Loading
Loading